Ní ilé kọjú sími kọjú síọ kan ni àdúgbò agbowó, ilẹ̀ ti n su, òrùn si ti n re ibi àti wọ. Fun ìdí èyí, ọpọ nínú àwọn obìnrin ti n gbé nínú ile olójúlé mẹ́fà yìí ni wọn ti délé láti ibi isẹ, ẹni tí o sisẹ nínú wọn na wa nílé.
O dàbí pé àwọn ọkọ wọn o ti de sùgbọ́n àwọn ọmọ re tí wọ́n se ròyànròyàn kiri láàrin ẹ̀dẹ̀. Irú àsìkò yi gan ni ìran àwọn ìyàwó ilé yi dun wo. Kísìnì ni ìran wa, yàrá kólóbó kan báyìí ni ẹ̀hìnkùlé ni ìyẹn wa, àsìkò kan na ni gbogbo wọn n wa óúnjẹ alẹ si.
Wọn a ma fi ìdí gbòdí, wọn a si ma jẹ orísirísi ẹjọ lẹnu ti óúnjẹ o fi jìnnà. Méjì nínú àwọn ìyàwó ilé yi kìí da si gbogbo rọ̀bọ̀rebe yi sa, àwọn mẹrin ni ẹ o ba ni kísìnì ni iru àsìkò ti mo n sọ yi ko to di pe àrin wọn padà daru.
"Iya Rámọ́, o pẹ́yin jáde larọ yi o" Iya Grace kọjù si Iya Rámọ́ bo ti n sọ ikoko ọbẹ̀ lori sítòfù. "Bóyá yàrá pálọ̀ ni wọn sùn" Iya Kabira sáré da Iya Grace lohun. Gbogbo wọn bu sẹrin, wọn tun ba ọ̀rọ̀ lọ bi wọn ti n dáná.
Nígbà tí Iya Rámọ́ ó fọhùn, o ni "Dádì wa ni o, ahh! ìsọwọ́ ti wọn fi wó mi mọ́júmọ́, o kọjá bẹ́ẹ̀...ìlùkulù ni alágbẹ̀dẹ abẹ wọn lu mi, gbogbo ara lo wó mi."
Gbogbo wọn tun gbe ẹ̀rin, iya Grace ni alabajọ ti ara ilé òhun fi pẹ ji. Bi yẹ̀yẹ́ ti n wọra, Iya Kòtóǹkan ti ko sọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀ na lahùn, o kọjú si Iya Rámọ́, o tun ìró to ta mọ́ àyà so, o ni " Ẹ̀yin ma n gbádùn gan o, wọn n jẹ iṣẹ́ yin dáadáa, ọkọ mi baba
Kòtóǹkan káre níbi tó wà. Súkẹ́súkẹ́ to ba se báyìí, omi ni mo fi n lo ìyókù."

Bi àwọn to ku se gbọ eyi ni wọn ba fi igbe ta, "oró oooo."
- The story continues. | 📝Ayo Adams.
Check out this story too. Thank you. 😌 https://twitter.com/theayoadams/status/1264555146274656256?s=19
You can follow @theayoadams.
Tip: mention @twtextapp on a Twitter thread with the keyword “unroll” to get a link to it.

Latest Threads Unrolled: